16/02/2026
••••••AROFỌ••••••••
♠Àjò lAyé♠
Àjò layé, ará mi ẹ jẹ́ ká mọ̀,
Ayé lojà, ọ̀run nilé.
A wá kẹ́rù, a wá tà, a wá rà,
Ẹni bá rà títí, á padà sílé lọ fèsì.
Bí a bá jí lówúrọ̀, a kì í mọ ibi oòrùn yóò wọ̀ sí,
Nítorí ọmọ káríka kò mọ ibi tí ọmọ onílẹ̀ gbé fẹsẹ̀ tẹ́.
A bẹ̀rẹ̀ ìrìn pẹ̀lú ẹkún ní jọ́ kan,
A ó sì parí rẹ̀ pẹ̀lú dídákẹ́ ní jọ́ kan.
Àpò kò kún fún ayérayé,
Bí a bá rìn títí, ẹsẹ̀ á rẹni, a ó sì dẹ́rù tì.
Ẹ wo bí ayé ṣe rí!
Irú ẹni tí a rí lówúrọ̀, a kì í rí i mọ́ lálẹ́.
Ènìyàn fẹ́ tẹ ayé mọ́lẹ̀,
Ó gbà pé òun nìkan ló gbọ́n,
Ṣùgbọ́n ó gbàgbé pé egungun tí ó bá ga jù, ajá ni yóò gbé e.
A kìí rìn kí a má mi kan,
A kìí lù láyé kí a má dún,
Ṣùgbọ́n rántí pé, atọ́ka tí ó nù, kò lè mọ̀nà ilé mọ́.
Àjò layé, ẹ fura!
Ma ṣe fowó ṣe ìkà, ma ṣe fọlá fínràn,
Nítorí ẹni tí ó bá sùn lórí ẹní, yóò padà sùn lórí ilẹ̀.
Bí a bá kúrò lọ́jà, ohun tí a rà ni a ó gbé lọ́wọ́,
Ẹni bá gbin rere, rere ni yóò kà,
Ẹni tí ó bá sì gbin ẹ̀gún, kò ní kà á ní òwú.
Kí a tó rìn kọjá, ẹ jẹ́ ká fi ohun rere sílẹ̀,
Kí orúkọ wa má baà bàjẹ́ bí omi tí ó dà sínú yanrìn.
Nítorí ayé lọjà, ọ̀run nilé,
Gbogbo wa pátá, àjòjì ni wá
© Bámgbọ́pàá