06/06/2022
GOOD MORNING TO YOU ALL
ORI....(DESTINY,FATE,).
~Iwonran olokun, abara le kokooko bi ota,
~Difa fun Ori Apere
~Omo atakara sola
~Nje ibi ori gbe ni owo
~Akara, Ori je won o ka mi mon won, Akara!
~Nibi ori gbe ko'le
~Akara, Ori je won o ka mi mon won, Akara!
~Nibi ori gbe nni ire gbogbo
~Akara, Ori je won o ka mi mon won, Akara!
~Ori apeere, ori apesin,
~Iwa ni finin joye, Ori ni finin joba,
~Ori ni bani rogun tafi nsegun,
~Aba fi orisa sile, Ori lababo,
~Ojo Ori ngbeni nibo ni orisa wa,
~Eni Ori ba base ni taja, ni jere, ni kere oja dele,
~Nba tete mon pe Ori ni uba tima saagun,
~Ase ori eni ni gbe ni,
~Oogun lolojo kan iponju, Ori lolojo gbogbo,
~Ori agbe logbe pade alaro,
~Ori aluko logbe pade olosun,
~Ori lekeleke logbe pade elefun.
~Ori mi gbemi pade ire.
~Ibi oju ibi, base bi eru labi Omo-oba,
~Ori tiwon gbe waye lotooto,
~Sebi ojo toro si ewuro loro si ireke,
~Ohun gbogbo lowo Ori,
~Ori logbe aje fun olokun,
~Ori logbe iyo fun olosa,
~Ori latonan eni wasaye,
~Ba bimon tuntun amun Ori waye,
~Aba bo egun ile, k'abo orisa oja, afi k'abo ori eni,
~Bi aba ra fila etu, ta sin ade ide, Ori laafi de,
~Ori ni baba ara,
~Isebo ni isogun, ba se waye pe aori laari,
~Ohun gbogbo lowo Ori,
~Ori leja fi nlabu, Ori lemon fi nla opo,
~Eye onifo ko fi Ori sogi, Sebi Ori ni,
~Ori leleda eni, Ori lalabaro eni,
~Ori mi jafun mi, eleda mi gbeminija,
~Apari inun mi mon ba tode je
~Iwa mi maje kori ta ko mi
~Eleda mi ma sun
~Ori adiye oniburu koye dudu
~Ori lafi umun eran lawo
~Oojo layan ipin, ojo kan layan Ori
~Akunleyan, akunlegba ati ayanmo
~Akunleyan lohun ta yan pe afe je l'aye
~Akunlegba lonan ta yan pe aofi je ohun tafe je laye
~Ayanmo lohun ti ayan ti o se yi pada
~Ayanmo o gbo oogun, ori lelejo
~Ori koni ohun ogbe ni, amon apari inun(Iwa) uko?
~Ibi kan soso ni 'Oriseki' 'Liemere' ati 'Afuwape' ti yan ori
~Amon apari inun Afuwape gbe e
~Loba dara fun ju gbogbo won lo
~Ni won bani 'awon omon ibi Afuwape gbe yan ori awon oba
lo yan tawon'
~Afuwape ni 'ibi kan lagbe yan ori, kadara o papo ni'
~Ori mi gbe ki nlowo
~Eleda mi lami kin lola
~Ori mi gbe mi
~Ori mi la mi
~Gbemi atete niran
~Gbemi atete gbeni ku foosa
~Ori nii gbe ni
~Ajawo, kii se oosa.
~Ori wo ibi ire ki o gbe mi de
~Ese wo ibi ire ki o sin mi re
~Ibi ope agunka ngbe mii re
~Emi ko mo ibe
~Difa fun Sasore
~Eyi to ji ni Kutukutu owuro
~Nje ti o ba tun ku ibi to dara ju eyi lo
~Ori mi ma sai gbe mi de ibe.
~Ori se mi lolowo, eleda mi semi l'olola
~Ori mase mi lerun, eleda mi mase mi ni iwofa
~Ori mi jafunmi, elada mi masun
~Ori mi ma gbagbe mi, elada mi magbabode
~Ire ni moyan nile Ajala-mopin, nibi kaluku ti yan ori
~Adeda, aseda, iba re Olodumare.
Ire oooooo!
Ela ború
Èlà Boyé
Èlà bọ ṣiṣe
Join my watsapp class with 2000 naira and have free access to ask any question about Herbs, Health, Marriage, Relationship and S3x. Send watsapp message to ☎️+2348133486496